ORIKI BASORUN FAJIMI
Oriki Basorun Fajimi
Oora tii gbaaye ra si
Oloooro,joko-jodo,
Orugu-ndu osan ti Ibo laarin oganjo
Aramo oba gba,Aremo oba ko
Adeshina igi n’ dal
Omo yerombi Akasa-nija
A Bonisee di kun un
A bolokee fa a dugbedugbe
A belegbodo te e muye muye.
Olooro! Iko lokun
Adeshina Alasida
O gbe’bikan le’ni
Orimurimu sambata
Ekun aseke!
Oloooro! Joko-jodo
Apata pete oke Akesan
O n reti eni ti yio ko ‘un(ko ohun)
Bi yio wo’do ,ariwo!
Bi yio goke,ariwo
O-fese- mejeeji- soju omi
rukurukuruku,oko ibeji
O-gboran-ija –ta –kiji,oko laperi.
Bi o ba demure ija tan,
Eni meeta lo o jo:
O mu waju jo olupon
O fakeyinsi jo siaba –ikooko,
Baba ko jo niyan lasan
Bi omo agunloye to soyo ro
Ojo ko tojo to o ri soja loja –iba
Gbogbo Baale- Baale lo n su saso,
Gbogbo agba Ibadan lo n su si sokoto.
					
